ÀṢEYỌRÍ GBOGBO WA LÁPAPỌ̀-ÀPILẸ̀KỌ ÌKÍNI LÁTI ỌWỌ́ RT. HON. ABÍỌ́DÚN ISIAQ AKÍNLÀDÉ
Tìdùn
nútayọ̀ àti ìbọláfúnni, mo fi ọpẹ́ ńlá fún Ọlọ́run Ọba, Olóore-Ọ̀fẹ́ Aláàánú-jùlọ, lórí oore ńlá kàǹkà tí Ó ṣe fún mi láti jáwé olúborí ní Ilé-Ẹjọ́-Kò-tẹ́-mi-lọ́rùn, tí ó wà ní ìlú Ìbàdàn, ní èyí tí ìgbẹ́jọ́ ti wáyé lórí ipò tí mo ń díje fún lábẹ́ Ẹgbẹ́ Ìṣèlú All Progressive Congress ní Ẹkùn Gúúsù-Yewa/Ìpókiá fún Ilé-Ìgbìmọ̀ Aṣòfin-Àgbà, nínú ìdìbò Ìjọba Àpapọ̀ tí ń bọ̀ lọ́dún 2023.
Bí ènìyàn bá gùn ẹṣin kọjá nínú mi, kò lè kọsẹ̀, nítorí pé, mo moore púpọ̀ sí Ọlọ́lá-jù-lọ, Ọmọọba Dàpọ̀ Abíọ́dún MFR, tí ó jẹ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ògùn, fún akitiyan àti àtìlẹ́yìn rẹ̀ ní àkókò náà. Gómìnà ni èjìká-tí-kò-jẹ́-kẹ́wù-ó-bọ́ fún mi, ni mo fi gbà pé Adarí rere àti aṣáájú pàtàkì ni o jẹ́.
Mo tún fi ìdùnnú àti ayọ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ Bàbá gbogbo wa, Olóyè Olúṣẹ́gun Ọ̀ṣọbà, mo sì tún kí igbá-kejì Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ògùn, Amojú-Ẹ̀rọ Noimot Sàlàkọ́ àti Ọ̀gbẹ́ni Tàlàbí SSG pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tí wọ́n jẹ́ alánìíyàn rere.
Gbogbo akitiyan àti àtìlẹ́yìn tí àwọn Adarí-Ẹgbẹ́ APC Àpapọ̀ àti Ìpínlẹ̀ Ògùn ṣe fún mi náà kò ṣe é fi ojú parẹ́ nínú àṣeyọrí yìí.
Mo kí àwọn Amòfin tí wọ́n ṣe iṣẹ́ takuntakun láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé ìparí lábẹ́ Amòfin-Àgbà tí ó jẹ́ Kọmíṣánnà fún Ètò-Ìgbẹ́jọ́, ìyẹn Ọ̀gbẹ́ni Olúwaṣínà Ògúngbadé SAN. Oore ńlá gbáà ni o se fún mi. Mo dúpẹ́ dúpẹ́ oo.
Gbogbo ẹ̀yin Ọ̀gá mi, ẹ̀yin àgbààgbà, àti gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ wa ninu Ẹgbẹ́ Àtàtà, APC ti Ẹ̀ka-Ìwọ̀-Oòrùn Ìpínlẹ̀ Ògùn àti Gúúsù-Yewa/Ìpókiá, ni mo rí akitiyan tí gbogbo yín ṣe. Mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ yín o.
Gbogbo ẹ̀yin olólùfẹ́ mi, ẹ̀yin alátìlẹ́yìn mi nílé, lóko àti lẹ́yìn odi Nàìjíríà, ẹ̀yin Ìgbìmọ̀ Akínlàdé, ẹ̀yin mọ̀lẹ́bí mi àti gbogbo ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ̀yin Olùdarí SWAGA, ẹ̀yin olùdarí ìkànnì wa gbogbo, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín lọ́kọ̀ọ̀kan. Mo gbọ́dọ̀ dúpẹ́ ní àrà ọ̀tọ̀ lọ́wọ́ gbogbo àwọn Ìyálọ́jà, àwọn oníṣòwò, àwọn oníṣẹ́-ọwọ́, àwọn Amojú-Ẹ̀rọ, gbogbo Ìgbìmọ̀ Lèmọ́mù àti Àlùfáà, Àjọ Ọmọlẹ́yìn-Jésù, àwọn Ìgbìmọ̀ Ọ̀dọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́, àwọn Olùkọ́, àwọn CDA, àwọn Ọba Aládé, àwọn Baálẹ̀ àti gbogbo àwọn yòókù lápapọ̀. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo yín fún iṣẹ́ takuntakun tí ẹ ṣe, bí ẹ ti ń pè mí lórí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀, tí ẹ dá mi lọ́kàn le pé kí n fi ọkàn balẹ̀ àti gbogbo ààwẹ̀ pẹ̀lú àdúrà tí ẹ ṣe fún mi. Oore ńlá gbáà tí ẹ ṣe wọ̀nyí, n ò ní ya aláìmoore oo.
Àṣeyọrí wa ní Ilé-Ẹjọ́-kò-tẹ́-mi-lọ́rùn ni mo fi sọrí Èdùmàrè, gbogbo àwọn tí a jọ díje ní ipele àkọ́kọ́ àti gbogbo àwọn olólùfẹ́ wa nínú ẹgbẹ́ APC.
A ti borí ní ipele àkọ́kọ́ báyìí. Ìṣọ̀kan àti àjùmọ̀ṣepọ̀, àṣeyọrí wa lórí ìdìbò àpapọ̀ ní ọdún 2023 yóò so èso rere. Mo wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí gbogbo wa láti gbàgbé gbogbo ohunkóhun yòówù kí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, kí a sì ṣe ara wa ní ọ̀kan láti ṣe iṣẹ́ papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ẹgbẹ́ APC kan ṣoṣo. Bí mo bá ti ṣẹ ẹnikẹ́ni nípasẹ̀ ìwà tàbí ohunkóhun, ẹ dákun, ẹ ṣe àmójúfò fún mi, kí ẹ gbà pé Ọlọ́run nìkan ni ó gbọ́n jù lọ.
Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn mi ní agbègbè Gúúsù-Yewa/Ìpókiá lábẹ́ Ìjọba Àpapọ̀, mo mọ̀ dájú pé, bí ó ti wù yín láti jẹ́ kí n jáwé olúborí nínú ìdìbò Ìjọba Àpapọ̀ tí ń bọ̀, kí n lè dara pọ̀ mọ́ Ìgbìmọ̀ Aṣòfin-Àgbà, ó fi hàn pé yóò so èso rere fún ìdàgbàsókè lórí ètò ìjọba àwaarawa, tí yóò sì tún pèsè àǹfààní onírúurú àwọn ohun amáyédẹrùn. Bákan náà, bí ẹ ti mọ̀ mí sí Bàbá Ọmọ Kéékèèké, ÌPÈSÈ IṢẸ́ LỌ́PỌ̀LỌPỌ̀ FÚN ÀWỌN Ọ̀DỌ́ WA yóò túbọ̀ wáyé.
Mo gba gbogbo wa ní ìmọ̀ràn láti tú yááyá jáde fún ìpolongo Ẹgbẹ́ wa, APC nínú ìdìbò tí ń bọ̀ lọ́nà yìí. Ẹ jẹ́ kí a fọwọ́ sowó pọ̀ láti borí àwọn Ẹgbẹ́ alátakò wa ní gbogbo ọ̀nà.
Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ mí tẹ́lẹ̀, ìwà àti ìṣesí mi náà kò tíì yí padà. Bí mo jẹ́ onítẹríba, aláàánú àti akíkanjú ẹ̀dá fún àṣeyọrí àwọn ènìyàn mi ní Ẹkùn Ìwọ-Oòrùn Ìpínlẹ̀ Ògùn. MO JẸ́JẸ̀Ẹ́ PÉ Ń Ò NÍ DÓJÚ TÌ YÍN NÍ GBOGBO Ọ̀NÀ.
Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ gbogbo ẹ̀yin olólùfẹ́ mi. Gbogbo wa pátá ni a jọ ni àṣeyọrí yìí.
Èmi ni tiyín tòótọ́,
Rt. Hon. Abíọ́dún Isiaq Akínlàdé
Olùdìje lábẹ́ Ẹgbẹ́ All Progressive Congress
Fún ipò Aṣojú Ilé-Ìgbìmọ̀ Aṣòfin-Àgbà
Ní Ẹkùn Gúúsù-Yewa/Ìpókiá.
Ẹ ṣeun mi oo.
No comments:
Post a Comment